Categories
Yoruba

Àwọn Àfọ̀njá, Ọ̀dàlẹ̀, Ìkà, Agbẹ̀hìnbẹbọjẹ́ Fẹ̀ Da Àmọ̀tẹ́kùn Rú Lati Ọwọ Bámidélé Adémólá-Ọlátẹ́jú

Nígbà tí wọ́n dá agbófinró Hisbah sílẹ̀ ní Òkè Ọya, ǹjẹ́ ẹ gbọ́ kí àwọn ènìyàn wọn pariwo? Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ kí ọmọ wọn nínú Ọlọpa tàbí nínú Ọmọ Ogun Naijiria gbìmọ̀ láti dàárú? Àwọn agbẹ̀hìnbẹbọjẹ́ ilẹ̀ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n tí ń pète-pèrò láti gbógun ti àwọn Gómìnà wá lórí ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn.

Ẹ wá gbọ́ o. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dá ilẹ̀ Yorùbá lórí ààbò, ìgbéga, ìlera tàbi ìlọsíwájú, ilẹ̀ a gbé wọn mì. Àwọn Irúnmọlẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá a ṣe wọn mọ́’ṣẹ́. Bí òru, bí òru ló ń ṣe aláṣọ dúdú. Bí òru, bí òru, kó ń ṣe eku inú agbè. Ìmọ̀ wọn a di dúdú. Ìmọ̀ wọn kò ní jọ. Ìtàkùn to ni k’ érin má g’òkè ni wọn. A ti ṣe eléyìí ná. Kò níí dáa fún yí. Òfò ni omi ẹ̀kọ́ ńṣe. Òfò àti àdánù lẹ máa ṣe.

Àwọn ọkọ̀ wá ti ń lọ sí Ibadan. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni wọn máa lọ. Àyúnlọ, àyúnbọ̀ lọ̀wọ́ ń y’ẹ́nu.

Facebook Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *